مَا مَعِي وَجَهْ قَابِل بِهْ سِوَى حُسُنْ ظَنِّي
N kò ní ohun kankan láti fi kàjú rẹ àfi ìrètí rere mi nínú rẹ.
Yo
مَا مَعِي وَجَهْ قَابِل بِهْ سِوَى حُسُنْ ظَنِّي
فِيكْ يَا رَبِّ فَارْحَمْنِي وَلَا تَمْتَحِنِّي
Mi ò ní ohunkóhun tí mo lè fi kojú Yín ju ìrètí rere mi nínú Yín
Nítorí náà, Olúwa mi, ṣàánú fún mi, kí O má sì dán mi wò
تُبْتْ يَا رَبِّ فَاقْبَلْ تَوْبَتِي وَاعْفُ عَنِّي
وَامْحُ ذَنْبِي وَسَامِحْ كُلَّ تَقْصِيرْ مِنِّي
Mo ti ronúpìwàdà, Olúwa mi, gba ìrònúpìwàdà mi kí O sì dáríjì mí
Pa ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ, kí O sì fojú fò gbogbo àléébù mi dá
خِفِتْ مِنْ عَاقِبَةْ أَمْرِي فَجُدْ لِي بِأَمْنِي
مَحِضْ فَضْلٍ وَإِحْسَانٍ وَجُودٍ وَمَنِّ
Ẹ̀rù ohun tí òpin mi yóò jẹ́ ń bà mí, fún mi ní ìfọ̀kànbalẹ̀ látara oore Rẹ
Nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, ìṣoore, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn, àti ojú rere
آه مِنْ عَثْرَتِي يَا رَبِّ مِنْهَا أَقِلْنِي
زَادْ ذَنْبِي وَمِنْ كُثْرِ الْخَطَا حَارْ ذِهْنِي
Áà, Olúwa mi, nítorí ìkọsẹ̀ mi, gbé mi dìde kúrò nínú rẹ̀
Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀, ọkàn mi sì ti dágìrì látara ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe mi
أَدْرِكْ أَدْرِكْ بِتَعْجِيلِ الْفَرَجْ وَانْتَقِدْنِي
وَاعْطِنِي عِلِمْ مِنْكَ يَا إِلَهِي لَدُنِّي
Wá ràn mí lọ́wọ́, wá ràn mí lọ́wọ́, yára mú ìtura wá kí O sì gbà mí là
Sì fún mi, Ọlọ́run mi, ní ìmọ̀ àmúwá láti ọ̀dọ̀ Rẹ
يَنْجَلِي بِهْ عَنِ الْقَلْبِ الْصَّدِى كُلَّ رَيْنِ
ياَ سَمِيعَ الْدُّعَاءْ سَلْكَ اسْتَجِبْ وَاسْتَمِعْنِي
Èyí tí yóò mú gbogbo ìpata àti ìbòjú kúrò nínú ọkàn
Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, jẹ́ mi, kí O sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi
مَا لِي إِلَّا أَنْتَ مُعْطِي
مَا لِي إِلَّا أَنْتَ مُغْنِي
Mi ò ní ẹnikankan bí kò ṣe Ìwọ láti fún mi
Mi ò ní ẹnikankan bí kò ṣe Ìwọ láti sọ mí di ọlọ́rọ̀