صَفَتِ النَّظْرَهْ
Ìran náà mọ́
Yo
صَفَتِ النَّظْرَهْ طَابَتِ الْحَضْرَةْ
جَاءَتِ الْبُشْرَى لِأَهْل اللهِ
Ìran náà mọ́, ìpéjọpọ̀ náà sì dùn
Ìròyìn ayọ̀ ti dé fún àwọn ènìyàn Ọlọ́hun
قَامُوْا سُكَارَى لِذِي الْبِشَارَه
جَعْلَوْا عِمَارَهْ شُكْراً لِلّهِ
Wọ́n dìde bí ọ̀mùtí fún ìròyìn ayọ̀ náà
Wọ́n sì kún inú ibẹ̀ pẹ̀lú ìjọ́sìn fún ọpẹ́ Ọlọ́hun
أَيُّهَا الْحَاضِرْ اُذْكُرْ وَذَاكِرْ
إِيَّاكَ تُنْكِرْ حَالَ أَهْلِ اللهِ
Ìwọ tí o wà níhìn-ín, rántí kí o sì ṣe ìrántí
Ṣọ́ra kí o má ṣe sẹ́ ipò àwọn ènìyàn Ọlọ́hun
فَسَلِّمْ لَهُمْ فِيمَا عَرَاهُمْ
وَاعْلَمْ أَنَّهُمْ غَابُوْا فِي اللهِ
Ju-wọ́-sílẹ̀ fún wọn nínú ohun tí ó bá bò wọ́n
Mọ̀ pé wọ́n ti pòórá sínú Ọlọ́hun
فَالْوَجْدُ بِهِمْ دَاعِيْ يَدْعِيْهِمْ
يَطْرَأْ عَلَيْهِمْ فِيْ ذِكْرِ اللهِ
Nítorí ìdùnnú-àròyìn jẹ́ olùpè tí ó ń pè wọ́n
Ó sì ń dé bá wọn nínú ìrántí Ọlọ́hun
وَمَنْ لَمْ يَجِدْ فَلْيَتَوَاجَدْ
قَصْداً يَتَعَرَّضْ لِفَضْلِ اللهِ
Ẹni tí kò bá rí ìdùnnú-àròyìn, jẹ́ kí ó wá a
Pẹ̀lú èrò láti fara han oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́hun
هَكَذَا قَالُوْا وَلِذَا مَالَوْا
وَلَقَدْ غَالُوْا فِي ذِكْرِ اللهِ
Báyìí ni wọ́n sọ, nítorí èyí ni wọ́n ṣe fì
Wọ́n sì kọjá ààlà nínú ìrántí Ọlọ́hun
حَتَّى قَدْ ظَنَّا مَنْ لَيْسَ مِنَّا
أَنَّا جُنِنَّا بِذِكْرِاللهِ
Títí tí àwọn tí kì í ṣe ara wa fi rò
Pé a ti ya wèrè nítorí ìrántí Ọlọ́hun
هَنِيْئاً لَنَا ثُمَّ بُشْرَانَا
إِنْ كَانَ لَنَا حُمْقٌ فِي اللهِ
Alábùkún-fún ni wá, ìròyìn ayọ̀ sì ni fún wa
Bí "iwèrè" wa bá jẹ́ nítorí Ọlọ́hun