مَا لِلْنِّيَاقِ إِذَا حَدَا جَمَّالُهَا
Kí ni ó dé fún àwọn abo-ìbákasẹ nígbà tí olùdarí wọn bá ń kọrin sí wọn?
Yo
Yo
مَا لِلْنِّيَاقِ إِذَا حَدَا جَمَّالُهَا
تَدَعُ الْعَنَاءَ وَلَا تَمَلُّ مَلَالَهَا
Kí ló dé fún àwọn ràkúnmí nígbà tí awakọ̀ wọn bá ń kọrin fún wọn?
Wọ́n ń ju àárẹ̀ nù, wọn kò sì ń rẹwẹ̀sì nínú ìrìn-àjò náà.
وَتَرَىٰ لَهَا فِي السَّيْرِ جِدًّا وَاضِحًا
شَوْقًا تَمُدُّ يَمِينَهَا وَشِمَالَهَا
Ìwọ yóò rí ìtara tó ṣe kedere nínú ìrìn wọn
Nítorí ìyánhànhàn ni wọ́n ń na apá ọ̀tún àti òsì wọn.
وَتَبَاشَرَتْ لَمَّا أَتَتْ بَدْرًا رَأَتْ
نُورَ النَّبِيِّ الْهَاشِمِيِّ بَدَا لَهَا
Wọ́n kún fún ayọ̀ nígbà tí wọ́n dé Badr tí wọ́n sì rí
Imọ́lẹ̀ Ànábì ará ìdílé Hashim tó hàn sí wọn.
غَنِّ لَهَا يَا سَعْدُ بِاسْمِ مُحَمَّدٍ
فَلَعَلَّهَا تُصْغِي لِمَنْ غَنَّىٰ لَهَا
Kọrin fún wọn, ìwọ Sa‘du, pẹ̀lú orúkọ Muhammad
Bóyá wọn yóò fetí sí ẹni tí ó ń kọrin fún wọn.