Yo
الله الله الله الله سَيَّدِي الله
الله الله الله اَلْعَظِيْمُ الله
Allahu Allahu Allahu Allahu Olúwa mi Allahu
Allahu Allahu Allahu Ẹni-Nlá ni Allahu
أَيَا مُرِيْدَ اللهُ نُعِيدْ لَكْ قَوْلِ اصْغَهْ
إِذَا تَفْهَمْ قَوْلِي بِهِ تَصِلْ لِلّهْ
Ìwọ olùwádìí Allahu, a ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún ọ, gbọ́ ọ
Bí òye ọ̀rọ̀ mi bá yé ọ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni wàá dé ọ̀dọ̀ Allahu
عَلَيْكَ يَا مُرِيدْ بِخَمْرَةِ التَّوْحِيدُه
وَإِنْ تَبْغِ الْمَزِيدْ فَالْغَيْرُ عَنْكَ انْسَهْ
Ó jẹ́ dandan fún ọ ìwọ olùwádìí pẹ̀lú ọtí imọ̀-ọ̀kan-ṣoṣo
Bí o bá sì ń fẹ́ ìfikún, gbàgbé ohun mìíràn yàtọ̀ sí Òun
فَاذْكُرْ الاسْمَ الْأَعْظَمْ وَاطْوِ الْكَوْنَ تَغْنَمْ
وَخُضْ بَحْرَ الْقِدَمْ فَذَاكَ بَحْرُ الله
Pe Orúkọ t'ó ga jùlọ, kí o sì ká ayé jọ kí o jèrè
Bọ́ sínú òkun-ìṣáájú, nítorí pé ìyẹn ni òkun Allahu
وَخُضْ بَحْرَ الْأَنْوَارْ وَالْمَعْنَى وَالْأَسَرَارْ
وَافْنِ هَذِي الدِّيَارْ يَبْلُغْ قَلْبُكْ مُنَاهْ
Bọ́ sínú òkun àwọn ìmọ́lẹ̀, ìtumọ̀, àti àwọn àṣírí
Pa ayé yìí rẹ́ lọ́kàn rẹ, ọkàn rẹ yóò sì dé ibi ìfẹ́ rẹ̀
وَلْتَفْنَ في الْمَعْبُودْ تَذُوقْ مَعْنَى الشُّهُودُ
إِذْ لَيْسَ ذَا الْوُجُودْ إِلَّا مِنْ نُورِ الله
Parẹ́ pátápátá nínú Ẹni tí a ń sìn kí o lè tọ́ ìtumọ̀ rírí Rẹ̀
Nítorí kò sí ìwàláàyè yìí, àfi láti inú ìmọ́lẹ̀ Allahu
الْمُلْكُ وَالْمَلَكُوتْ كَذَاكَ الْجَبَرُوتْ
فَكُلُهَا نُعُوتْ وَالذَّاتُ مُسَمَّاهُ
Ijọba ayé àti ti ọ̀run, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ijọba agbára
Gbogbo rẹ̀ jẹ́ àwọn àpèjúwe, Ẹni-gan-an ni a sì sọ lórúkọ
فَغِبْ عَنِ الصِّفَاتْ وَافْنَ في ذَاتِ الذَّاتْ
هَذِي تَلَوُّنَاتْ مَصِيرُهَا لِلِهُ
Parẹ́ kúrò nínú àwọn àpèjúwe, kí o sì parẹ́ nínú Ẹni-gan-an
Àwọn ìyípadà àwọ̀ ni ìwọ̀nyí, ọ̀dọ̀ Allahu ni òpin wọn
إِلَيْهِ الْمُنْتَهَى وَمِنْهُ الْمُبْتَدَا
وَالْآنَ قَدْ بَدَا وَالْكَوْنُ فِي حُلَاهْ
Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni òpin jẹ́, lọ́dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ti wá
Ní báyìí O ti farahàn, ayé sì wà nínú ẹwà Rẹ̀
لَهُ الْكَوْنُ مِرْآتْ وَمَظْهَرُ الصِّفَاتْ
مُحَمَّدْ نُورُ الذَّاتْ عَلَيْهِ صَلَّى الله
Dígí ni ayé jẹ́ fún Un àti ibi-ìfarahàn àwọn àpèjúwe
Muhammad ni ìmọ́lẹ̀ Ẹni-gan-an, kí ìkẹ́ Allahu máa bá a
الْعَلَاوِيْ يَقُوْلْ قَوْلًا مِنْهُ مَقْبُولُ
تَهِيْمُ بِهِ الْعُقُولْ تَغِيبْ فِي ذَاتِ الله
Al-Alawiy ń sọ ọ̀rọ̀ kan tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà
Àwọn iyè-inú ń dàmú nítorí rẹ̀, wọ́n ń parẹ́ nínú Ẹni-gan-an Allahu