يَا جَمَالَ النَّبِيِّ يَا حَنَانَ النَّبِيِ
O Beauty of the Prophet, O Compassion of the Prophet
Yo
يَا جَمَالَ النَّبِيِّ
يَا حَنَانَ النَّبِيِ
Ìfẹ́ t'Ànábì
Ìyọ́nú t'Ànábì
وَاللَّهِ الْعَظِيمِ يَا نَاسُ
مَا لِينَا غَيْرُ النَّبِيِ
Mo fi Ọlọ́run Ńlá búra, ẹyin ènìyàn
Kò sí ẹni tí a ní ju Ànábì lọ
مَا لِينَا غَيْرُهْ هُوَ
سَاكِن فِي الْقَلْبِ جُوَّة
Kò sí ẹni tí a ní ju òun nìkan lọ
Ó ń bẹ nínú ọkàn lọ́hùn-ún gangan
دَهْ حَبِيبي وَرُوحُي هُوَ
وَضَمَّنِي سَيِّدُنَا النَّبِي
Olólùfẹ́ mi àti ẹ̀mí mi ni òun ń ṣe
Olórí wa Ànábì sì gbà mí mọ́ra
مَا لِينَا غَيْرُهُ ثانِي
طَرْفُهْ أَكْحَلُ رَبَّانِي
A kò ní ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀
Ìwò ojú rẹ̀ jẹ́ títàn àtọ̀lọ́runwá
أَبْلَجُ وَرْدِيُّ الْوَجَانِ
حَبِيبُنَا سَيِّدُنَا النَّبِي
Ìmọ́lẹ̀ ń tàn lójú rẹ̀, ẹ̀yẹkẹ́ rẹ̀ sì pọ́n fẹ́rẹ́
Olólùfẹ́ wa, olórí wa Ànábì
مَا لِينَا غَيْرُ الرَّسُولِ
جَمَالُهُ يَسْبِي الْعُقُولَ
A kò ní ẹnìkan ju Òjíṣẹ́ náà lọ
Ẹwà rẹ̀ ń gba ọpọlọ àti òye lọ
نَظْرَةً يَا أَبَا الْبَتُولِ
جُدْ بِزَوْرَةٍ يَا نَبِي
Fún wa ní ojú àánú kan, ìwọ baba Bátúlù
Ṣe ojú rere kí o sì bẹ̀ wá wò, ìwọ Ànábì
كَفُّكَ يَا طَهَ طَاهِرُ
ذِكْرُكَ سِرُّ الْبَشَايِرِ
Àtẹ́lẹwọ́ rẹ, ìwọ Táhá, ó mọ́
Ìrántí rẹ ni àṣírí àwọn ìró ayọ̀
يَا جَابِرَ لِلْخَوَاطِرِ
اجْبُرْنَا يَا سَيِّدَنَا النَّبِي
Ìwọ tí o ń tu ọkàn tí ó bàjẹ́ nínú
Tù wá nínú, ìwọ olórí wa Ànábì
نُورُ الْمُصْطَفَى أَحْمَدُ
نُورٌ أَزَلِيٌّ سَرْمَدُ
Ìmọ́lẹ̀ Músùtáfà Áhímádù
Ìmọ́lẹ̀ ayérayé àti aláìlópìn ni
أَوَّلُ مَا رَبِّي أَوْجَدَ
نُورُكَ يَا سَيِّدَنَا النَّبِي
Ohun àkọ́kọ́ tí Olúwa mi dá
Ni ìmọ́lẹ̀ rẹ, ìwọ olórí wa Ànábì