لَمْ يَخْلُقِ الرَّحْمَنُ مِثْلَ مُحَمَّدٍ
Aláàánú kò dá irú Muhammad rí.
Yo
لَمْ يَخْلُقِ الرَّحْمَنُ مِثْلَ مُحَمَّدٍ
بَيْنَ الْوَرَى بَشَراً عَلَى الْإِطْلَاقِ
Oba Àjọ́kẹ́-ayé kò dá ẹni tí ó dàbí Muhammad
Láàárín gbogbo ẹ̀dá, kò sí ọmọ ènìyàn kankan rárá
كَلَّا وَلَا عَرَفَ الْخَلَائِقُ قَدْرَهُ
مَا فَوْقَهُ حَقّاً سِوَى الْخَلَّاقِ
Rárá o, àwọn ẹ̀dá kò mọ bí ọlá rẹ̀ ti tó
Kò sí ẹni tí ó ga jù ú lọ lótìítọ́ àfi Ẹlẹ́dàá
مَاذَا أَقُولُ بِوَصْفِهِ وَمَدِيحِهِ
وَسَنَاهُ دَوْماً بَاهِرُ الْإِشْرَاقِ
Kí ni mo lè wí nínú ìjúwe rẹ̀ àti ìyìn rẹ̀?
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì ń tàn yinrin pẹ̀lú dídán títí láé
وَهُوَ الَّذِي لِلْخَلْقِ أُرْسِلَ رَحْمَةً
وَأَتَى يُتَمِّمُ مَكَارِمَ الْأَخْلَاقِ
Òun ni ẹni tí a rán gẹ́gẹ́ bí ìkẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá
Ó sì wá láti mú ìwà ọmọlúàbí dé ìjẹ́-pípé