يَمِّمْ نَحْوَ الْمَدِينَةْ تَرَى الْأَنْوَارْ    
Kọjú sí ìhà Mẹ́dínà, wàá rí àwọn ìmọ́lẹ̀.
Yo
يَمِّمْ نَحْوَ الْمَدِينَةْ تَرَى الْأَنْوَارْ    
وَاقْصُدْ حِمَى نَبِيِّنَا طَهَ الْمُخْتَارْ
Kojú sí ìlú Madinah, wà á rí àwọn ìmọ́lẹ̀
Kí o sì wá ààbò nọ́dọ̀ Ànábì wa, Taha Àyànfẹ́
مُحَمَّدْ يَا أَبَا الْزَّهْرَا نَرْجُو نَظْرَةْ    
أَرَى الْقُبَّةَ الْخَضْرَا لَيْلًا وَنَهَارْ
Muhammad, ìwọ baba Zahra, a ńretí ìwò kan
Mo ńrí orù-ibojì aláwọ̀ ewé ní òru àti ọ̀sán
مُحَمَّدْ يَا أَبَا الْقَاسِمْ إِنِّي هَائِمْ    
عَسَى تَقْبَلْنِيْ خَادِمْ أَنَا وَالْحُضَّارْ
Muhammad, ìwọ baba Qasim, nítòótọ́ mo ti d’ẹni t’ífẹ́ ńdàrú
Bóyá o ó gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́, èmi àti gbogbo àwọn tí wọ́n wà níhìn-ín
فَامْدُدْ يَدَكْ وَالْبَاعَا وَالْذِّرَاعَا    
وَاطْلُبْ مِنْهُ الْشَّفَاعَةْ وَقْتَ الْأَسْحَارْ
Nítorí náà, na ọwọ́ rẹ, ìfà-ọwọ́ rẹ, àti apá rẹ
Kí o sì tọrọ ìpẹ̀tù lọ́dọ̀ rẹ̀ ní àsìkò ìfìyàrẹ́
وَقِفْ حَوْلَ الْضَّرِيحِ يَا فَصِيحِ  
وَاغْسِلْ قَلْبَ الْجَرِيحِ مِنَ الْأَْكْدَارْ
Kí o sì dúró yí ibojì mímọ́ náà ká, ìwọ afọ̀rọ̀-mọ̀-ọ́-sọ
Kí o sì fọ ọkàn tí ó ńdun kúrò nínú gbogbo ìbànújẹ́