اَلْهِجْرَةُ رِحْلَةُ هَادِيْنَا
Hijira ni ìrìn-àjò atọ́nisọ́nà wa
Yo
اَلْهِجْرَةُ رِحْلَةُ هَادِيْنَا
حَمَلَ الْإِسْلَامَ لَنَا دِيْنَا
Hijrah ni irin-ajo Olutọna wa
O gbe Isilaamu bọ fun wa gẹgẹ bi ẹsin
فَسَلَامُ اللّٰهِ عَلَی الْهَادِيْ
وَالْكَوْنُ يُرَدِّدُ آمِيْنَا
Ki ikini alaafia Ọlọhun maa ba Olutọna naa
Ki gbogbo agbaye si maa sọ pe "Amin"
رَحَلَ الْصِّدِّيقُ عَنِ الْدَّارِ
فِی صَحْبَةِ خَيْرِ الْأَبْرَارِ
Al-Siddiq kuro ninu ile rẹ
Ni ajọṣepọ pẹlu ẹni ti o dara julọ ninu awọn olododo
صَلَوَاتُ اللّٓهِ تُبَارِکُهُ
مَلَأَ الْدُّنْيَا بِالْأَنْوَارِ
Ki awọn ikini Ọlọhun maa bukun fun u
O si fi awọn imọlẹ didan kun gbogbo agbaye
اَللّٰهُ تَكَفَّلَ يَحْمِيْهِ
وَعَلِيٌّ أَصْبَحَ يَفْدِيْهِ
Ọlọhun funrarẹ lo ṣe onigbọwọ aabo rẹ
Ali si dide lati fi ẹmi rẹ ṣ'odindi fun u
وَبِسِرِّ الْقَوْمِ الْأَشْرَارِ
بِنْتُ الْصِّدِّيْقِ تُوَافِيْهِ
Pẹlu awọn aṣiri awọn eniyan buburu
Ọmọbinrin Al-Siddiq n lọ pade rẹ
وَصَلَ الْمُخْتَارُ إِلَی طَيْبَةْ
وَ الْكُفْرُ تَرَاجَع فِی خَيْبَةْ
Atayanyan de ilu Taybah
Aimọkan si padasẹyin ninu ijakulẹ
وَ جُنُوْدُ اللّٰهِ تُحِيْطُ بِهِ
مِنْ نُوْرِ الْاِسْلَامِ الْهَيْبَة
Awọn ọmọ ogun Ọlọhun si yi i ka
Pẹlu ọla-nla ti o wa ninu imọlẹ Isilaamu
بِالْرُّوْحِ سَنَحْمِی الْمُخْتَارا
وَ نُقَاتِلْ عَنْهُ الْكُفَّارا
Pẹlu ẹmi wa ni a o fi daabobo Atayanyan
A o si ba awọn alaigbagbọ jagun nitori rẹ
عَهْدًا لِلّٰـهِ نُبَايِعُهُ
جُنْدًا لِلّٰـهِ وَ اَنْصَارا
Adehun ni fun Ọlọhun ti a n ṣe ni jẹẹmọ
Gẹgẹ bi ọmọ ogun Ọlọhun ati awọn oluranlowo