حَيُّوا الْهَادِي بِأَجْمَلَ ذِكْرَى
Ẹ kí Olùtọ́sọ́nà pẹ̀lú ìrántí tí ó lẹ́wà jùlọ.
Yo
حَيُّوا الْهَادِي بِأَجْمَلَ ذِكْرَى
صَلُّوا مَعَنَا يَا حُضَّارْ
Ẹ kí Atọ́nà náà pẹ̀lú ìrántí tò dára jùlọ
Ẹ bá wa kí i, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín
فَهُوَ عِمَادِي يَوْمَ الْمَعَادِ
نَبِيُّنَا طٰهَ الْمُخْتَارْ
Nítorí òun ni alátìlẹ́yìn mi ní ọjọ́ àjíǹde
Ànábì wa Taha, Ẹni Àyànfẹ́
صَلُّوا مَعَنَا
Ẹ bá wa kí i
هٰذَا الَّذِي سَرَى لَيْلًا
ثُمَّ دَنَا فَتَدَلَّى
Ẹni tí ó rìn nínú òru
Lẹ́yìn náà ó súnmọ́, ó sì tún súnmọ́ sí i
وَهُوَ بِالْأُفُقِ الْأَعْلَى
حَبَاهُ الْوَاحِدُ الْسَّتَّارْ
Nígbà tí ó wà ní ojú-ọ̀run tí ó ga jùlọ
Ọ̀kan-ṣoṣo, Olùṣe-àṣírí, fún un ní oore Rẹ̀
فَهُوَ عِمَادِي يَوْمَ الْمَعَادِ
نَبِيُّنَا طٰهَ الْمُخْتَارْ
Nítorí òun ni alátìlẹ́yìn mi ní ọjọ́ àjíǹde
Ànábì wa Taha, Ẹni Àyànfẹ́
صَلُّوا مَعَنَا
Ẹ bá wa kí i
عَلَى الْعَرْشِ رَقَى الْجَمِيلْ
وَكَلَّمَهُ الْمَوْلَى الْجَلِيلْ
Ẹni Tò lẹ́wà náà gòkè lọ sí Orí-ìtẹ́
Olúwa Alápọ́nlé náà sì bá a sọ̀rọ̀
وَقَالَ أَبْشِرْ يَا خَلِيلْ
شَفَاعَتُكَ لِمَنْ تَخْتَارْ
Ó sì wí pé, “Yọ̀, ìwọ ọ̀rẹ́ mi àyànfẹ́
Ìṣẹfa rẹ wà fún ẹnikẹ́ni tí o bá yàn”
فَهُوَ عِمَادِي يَوْمَ الْمَعَادِ
نَبِيُّنَا طٰهَ الْمُخْتَارْ
Nítorí òun ni alátìlẹ́yìn mi ní ọjọ́ àjíǹde
Ànábì wa Taha, Ẹni Àyànfẹ́
صَلُّوا مَعَنَا
Ẹ bá wa kí i
صَلَّى مَوْلَانَا عَلَيْهْ
وَالْآلِ وَالصَّحْبِ لَدَيْهْ
Kí Olúwa wa kí i
Àti sórí àwọn ará ilé rẹ̀ àti àwọn ọmọ-lẹ́yìn rẹ̀
مَنْ جَاهَدُوا بَيْنَ يَدَيْهْ
وَنَوَّرُوا لَنَا الْأَفْكَارْ
Àwọn tí wọ́n saapa níwájú rẹ̀
Tí wọ́n sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òye wa
فَهُوَ عِمَادِي يَوْمَ الْمَعَادِ
نَبِيُّنَا طٰهَ الْمُخْتَارْ
Nítorí òun ni alátìlẹ́yìn mi ní ọjọ́ àjíǹde
Ànábì wa Taha, Ẹni Àyànfẹ́
صَلُّوا مَعَنَا
Ẹ bá wa kí i