صَلَّى عَلَيْكَ اللَّهُ يَا عَدْنَانِ
Ki Ike Olorun ma ba o, iwo Adnan.
Yo
صَلَّى عَلَيْكَ اللَّهُ يَا عَدْنَانِ
يَا مُصْطَفَى يَا صَفْوَةَ الْرَّحْمَٰنِ
Kí Ọlọ́run kẹ́ ọ, ìwọ àtọmọdọ́mọ Adnāni
Ìwọ Àyànfẹ́, ìwọ àṣàyàn Olùṣàánú
الْحَمْدُ لِلَّهِ الَّذِي أَعْطَانِي
هَذَا الْغُلَامَ الْطَّيِّبَ الْأَرْدَانِ
Gbogbo ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run ẹni tí ó fún mi
Ní ọmọdékùnrin oníwà-mímọ́ àti títayọ yìí
قَدْ سَادَ فِي الْمَهْدِ عَلَى الْغِلْمَانِ
أُعِيذُهُ بِالْبَيْتِ ذِي الْأَرْكَانِ
Ó ti ṣe ọ̀gá lórí àwọn ọmọdé láti inú jẹ̀lẹ́ńkẹ́
Mo fi ilé Ọlọ́run onígun-mẹ́rin dábò bò ó
حَتَّى أَرَاهُ بَالِغَ الْبُنْيَانِ
أَنْتَ الَّذِي سُمِّيتَ فِي الْقُرْآنِ
Títí tí n ó fi rí i tí ó dàgbà pípé nínú ìdúró
Ìwọ ni ẹni tí a dárúkọ rẹ̀ nínú Al-Ƙur’ān
أَحْمَدُ مَكْتُوبٌ عَلَى الْجِنَانِ
صَلَّى عَلَيْكَ اللَّهُ فِي الْأَحْيَانْ
Ahmad ni orúkọ tí a kọ sí ara àwọn ọgbà Ìdẹ̀ra
Kí Ọlọ́run kẹ́ ọ ní gbogbo àsìkò
أَحْمَدُهُ فِي الْسِّرِّ وَالْإِعَلْأَنِ
حَقًّا عَلَى الْإِسْلَامِ وَالْإِيمَانِ
Mo n fìyìn fún Un ní kọ̀rọ̀ àti ní gbangba
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ranyàn nínú Ìmàle àti Ìgbàgbọ́
يَا رَبَّنَا بِالْمُصْطَفَى الْعَدْنَانِ
اغْفِرْ ذُنُوبِي ثُمَّ أَصْلِحْ شَأْنِي
Ìwọ Olúwa wa, nítorí Àyànfẹ́ ọmọ Adnāni
Forí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn mí, kí O sì tún gbogbo ọ̀rọ̀ mi ṣe